Qlqrun Ti o Wa Pvlu Wa

“Kiyesii, wundia kan yóò lóyun, yóò si bí Qmọkunrin kan, wọn o máa pe orukọ rv ni Emanuvli, itumọ eyi ti i ze, Ọlọrun wà pẹlu wa.” (Matiu 1:22)

Lvvkan sii, Keresimesi de. Kii ze gvgv bii ohun itura ti yoo mara tuwa nigba ti wahala ba gba oju qjq, ti `banujv o sq pe oun ko si, nibi t`ayq ti jqba nigba kan ri. Kii ze bii ohun amaye-dvrun ti yoo gbvmi wa soke nigba ti ipqnju ti a ko le juwe ba gba qkan wa, t`omije n da poroporo loju, t’vru si kq, to ni afi ki oun fi qkan wa ze ile.

Keresimesi de! Kii ze ohun amaye-dvrun to le mu irora kuro nigba ti iru omi n halv lati gbewa min. Kii ze gvgv bii akoko ti imqlv ti kii ze ootq yoo muwa darapq pvlu okunkun, ti o diwa loju si ayq yoowu ti o le wa ninu aye.

Keresimesi de lati ran wa leti otiitq ti ko ni abula: Qlqrun ti a n sin ko takete siwa ninu aye, O wa ninu anito ti ko lvgbv, ogo nla si yi i ka, ogo ti abuku, vzv ohun èérí qmq eniyan kan ko lee fqwq kan.

Otiitq ni pe Qlqrun lo ga julq, kqja ayidayida aye yii, eyi ti gbedeke aye yii ko lee di I lqwq. O n jqba ninu alaafia pipe. Sibv, eyi kii sopin ohun ti a mq nipa Qlqrun.

Ni akoko Keresimesi, a ranti pe Qlqrun wqnu aye wa ti o ri palapala ati eyi to ti wq. Nitori ifv ti O ni fun izvda, Qlqrun ran Jesu Kristi, Qmq Rv sinu aye yii lati zi qna Ijqba qrun fun wa, nibi ti idanwo aye ko ti lee duro lvgbv anfaani t`qrun.

Jesu wa. O ri, O si ni iriri igbe-aye inira ti araye n zapa lati lo. O gboorun inira, O si ni imqlara ipo aini awqn vda. Oun ati awqn idile Rv l’aye koju vru ti azilo agbara ozelu, O tun jiya awqn ti wqn mulq si atipo.

Keresimesi lo de! Nigba ti Jesu si de, vgbv awqn angvli bu sorin; awqn oluzq-aguntan de lati papa, bvvni awqn amoye rin irin ajo lati qna jinjin lati wa ki i.

Qlqrun ti Jesu Kristi z’afihan lo ga julq – Vni to ga ju wa lq ni. Zugbqn Qlqrun yii tun wa pvlu wa – Oun lo wa lëgbêë, bvv naa l’O tun yiwa ka. Eyi ni Qlqrun ti o wa pvlu wa ninu aye ti o mu ibanujv, ijakulv ati ainireti bawa.

Iroyin ayq nla wa de fun gbogbo mutumuwa, ko yq awqn ti wqn ro pe awqn ti bq sinu panpv izoro silv. A ko dàwá làáyè wa. Qlqrun wa pvlu wa. Nigba ti Qlqrun si tqwa wa, ireti de fun wa, iyin ti qdq wa goke, ati ninu ikqju ija si awqn alazv ibi okunkun ayé yii, ati awqn vmí buburu oju qrun, a ni iriri alaafia, koda laarin iji.

Neville Callam
Gbogbogbo Akowe
Baptist World Alliance

(Translated nipa Supo Ayokunle)